C.M.S. 1, H.C. 2, L.M. (FE 19)
“Emi tikara mi yio ji ni kutukutu” – Ps 108:2
- Ji, okan mi, ba orun ji
Mura si ise ojo re;
Mase ilora, ji kutu,
K’o san gbese ebo oro. - Ro gbogbo ojo t‘o fi sofo
Bere si rere ‘se loni,
Kiyes’ irin re laiye yi;
K’o si mura d‘ojo nla ni. - K’oro re gbogbo j’otito
K’okan re mo b‘osan gangan
Mo p’Olorun nso ona re
O mo ero ikoko re. - Gba ninu imole orun
Si tan ‘mole na f’elomi
Jeki ogo Olorun re,
Han n’nu wa ati ise re. - Ji, gbon‘ra nu ‘ wo okan mi
Yan ipo re larin Angel
Awon ti nwon nkorin iyin
Ni gbogbo oru s’Oba wa. - Mo ji, mo ji, ogun orun
Ki isin yi s‘okan mi ji
Ki nle lo ojo aye mi
Fun Olorun mi bi ti yin. Amin