More

    CS Hymn 5: Wa s’adura oro

    C.M.S 7, H.C. t.H.C 258 S.M. (FE 22)
    “Lale loro ati losan li emi o ma gbadura” Ps. 55:7

    1. Wa s’adura oro
      Kunle k’a gbadura;
      Adura ni opa Kristiani,
      Lati b’Olorun rin.
    2. Losan, wole labe
      Apat’ aiyeraiye;
      Itura ojiji Re dun,
      Nigbat’ orun ba mu.
    3. Je ki gbogbo ile,
      Wa gbadura l’ale
      Ki ile wa di t’Olorun,
      Ati ‘bode orun.
    4. Nigbati od’oganjo
      Jek’a wi l’emi, pe
      Mo sun, sugbon okan mi ji
      Lati ba O sona. Amin