IBI JESU KRISTI.
-
ODE Kristi Olorun
Lat’ ibugbe rè rorun,
Lat’ ite alafia
Owá si aginju wa. - Om’ alade ‘lafia
Ode, ru iponju wa,
Ode, fi imolẹ rè
Pa õkun oru wa ré. - On Oba l’agbara de,
So aiye yi d’ilé rè,
Ode, reru ese wa,
On s’Olo’un at’eni - Ode, ti orukọ rè
Ro t’igbala fun aiyé,
Of’ ibugbe rè ayò
Silẹ ni ifẹ rè pọ.