IBI JESU KRISTI.
- K’ayin Oluwa t’ologo,
Loni l’abi (i) saiyé,
K’ayin (i) nitori ti omu
Ododo wa s’aiyé. - Awọn orile ede ni
Nreti Oluwa nã,
Nwọn fẹ ri ẹni t’awa ri,
Ani Olugbala. - Oba ati woli mimó
Nwọn foju si ọna,
N’ireti ati igbagbo
Nwọn duro d’Oluwa. - Şugbọn Eni ti nwọn reti,
Ani Olugbala,
Nigba ti wa ni awa ri (i)
Anrohin (i) y’aiye ka.