IBI JESU KRISTI
- JE korin si Olorun wa
Pelu Angeli re,
Angeli ko mọ ifẹ na,
Tawa gba lọwọ rè. - Ife’nu rere si awa
L’Olorun ti fi han,
Ati laiye alafia
Agbo lat’ orun wá. - Ore ofe t’on t’ododo
Laiye ni nwọn pade,
Nipa Jesu t’owá, tędo
N’iwa ‘relę laiye. - Ogo ni fun Olorun mi,
Tof ọmọ rẹ fun wa,
Tobojuwo iru eyi
Elese bi awa. - Laiye je k’afi iyin fun (u)
Nipa iwa rere,
Titi aofi ogo fun (u)
Lailese l’orun rẽ.