- Iwo low’ eni t’ire nșan,
Si o mo gbọkàn mi,
N’ibanuję mi aťędun
Oluwa ranti mi! - Nigba nkerora okàn mi,
Teșe mbe laju mi,
Oluwa dari mi ji mi
Ni ife ranti mi! - Idanwo kikan yi mi ka
Oluwa, nkòlẽ yẹ;
Oluwa fun mi lagbara,
Ni rere ranti mi! - Laisan ati ibinu ni
T’ara atokàn mi,
Fi suru fun mi, toju mi,
Si gbo! k’oranti mi! - Bi ‘tiju ati egan wá
Loju mi laiye yi,
Emi odoju ti ęgan,
B’iwo ba ranti mi. - Akoko iku sumo ‘le,
Mo jowo ara mi;
Olugbala ni d’emi mi,
Ngoke, k’oranti mi.