OLORUN ELEDA
- EJE k’ayin Olorun wa
Eleda gbogbo enia
At’eranko, at’eweko,
Ati gbogbo nkan mi gbogbo. - Otete se imolẹ nã,
K’ole fi iye laiye han,
Osi te oju orun lọ,
Kamá s’ofurufu nipo. - Enyin teloju, ewa, wo!
Aťoșupa, at’ irawo,
Lese ese l’ofi wọn si,
Iye won ni ale ka bi? - Eje k’awo aiye wa nã,
Ewa re, ti ofi bora,
Opo ju ogo Solomon,
T’ologo j’awọn Oba lọ. - Sugbon ju gbogbo rẹ lọ, wo
Enia l’aworan rè bo :
Emi ti Emi re ni nwọn,
Ofun wọn n’imò atogbọn. - Eje k’ayin Olorun wa,
Toda wa ni dara dara;
Eje ki gbogbo eda yin
Eleda, t’oto fun iyin.