More

    ORIN 4 – OLUWA tojo isimi

    OJO ISINMI

    1. OLUWA tojo isimi,
      Gbọ ti wa, pẹlu wa loni!
      T’ awa npade fun adua,
      Tangboro na, to fi fun wa.
    2. Isimi laiye l’ororun,
      Sugbon isimi t’ohun dùn,
      Lãlã okàn wa fe ‘jo na,
      T’ awa simi laileşẽ ‘da.
    3. Laiponju, lailare l’awà,
      Nib’ isimi, ti ombo wá,
      Ese, ibi kĩ debe na,
      Kiki alafia l’onsan.
    4. Kos’ ija, kosi ‘dagiri,
      Kos’ aniyan bi taiye yi,
      Todapọ mọ ikorin wa,
      T’ont’ ete aiku jade wá.
    5. Berẹ ọjọ t’atinreti,
      Afejumọ rẹ l’afë ri,
      Ona buru yi l’afẽ yọ,
      K’asun niku, k’aji layo.