OJO ISINMI
- Ojọ yi ni t’Olorun ya
Sọtọ fun isimi,
Je k’awa yo, k’ateriba
F’ Eleda t’ofun ni. - Jesu ti jinde lojo kan
Bi oni, lati mu
Ododo w’aiye, lati pa
Eșu t’on t’ese run. - L’ojo oni awọn ti rè
Npade fun adua,
Nwọn nkorin, nwọn si gbọrọ rè
Lati mọ ona na. - Nwọn ranti isimi ti mbo,
T’Olorun pese si
Orun rè, fun onigbagbo,
Ti yio duro șinşin.