IJIYA JESU KRISTI
- Ogo, olá ainipekun
Fi fun eni t’oti kú,
Iku rè t’awa jigbese
Lori igi t’ifibu;
Rohin iyin,
Rohin iyin,
Eni t’ogbelese la. - Ife Jesu t’akolẽ so,
Ainiye at’ailopin,
Enyin enia, ma’soro!
Opo, akolẽ wá ri;
Ogo ni fun,
Ogo ni fun,
Eni t’ogbelese la. - Nigba t’agbo itan ‘yanu
Niti agbelebu rè,
Amã korin si Olorun,
Ati sỌmọ mimó rè ;
Eni mimó,
Eni mimó,
Korin si oruko rệ.