Hymn 18 – Mo wi fun olukuluku
- Mo wi fun olukuluku
Pe, On ji osiyè,
Osi wà larin wa pelu,
Nipa Emi iyè. - Ewi fun enikeji nyin,
Ki nwọn ji pẹlu wa,
K’ imole kowa kakiri
Ni gbogbo aiye wa. - Nisisiyi aiyé yi ri
Bi ile Baba wa,
Iyè titun ti on fun ni,
Oso (o) d’ilé Baba. - Sinu okun ti ojin ju
Iberu iku bọ,
Ki gbogbo wa k’ole f’oju
Ba nkankan ti ombo. - Ona õkun ti On fi rin,
Mu ni lọ si orun,
Eni t’orin bi On ti nrin,
Yio d’odọ rẹ lọrun. - On yè, osi wà pẹlu wa
Ni gbogbo aiyé yi,
Ati nigba t’af’ara wa
F’erupę n’ireti.