Hymn 17 OLUWA jinde lõto
- OLUWA jinde lõto,
K’arohin rere nã,
Bi oti jiya lõto,
Tokú ni Golgata;
Sugbon odijo keta
Awọn Apostili
Ti nwọn w’oku Oluwa,
Laiye ni nwọn gbe ri (i). - Oluwa jinde lõto,
Ise lopari tan,
Iku rè mí iku wa
Nipa ajinde nã;
Nje nisisiyi owà
Laiye, ti ko kú mọ,
Ki, lehin iku ti wa,
Aoniye laikú mọ. - Oluwa jinde lõto,
Nje oro iku wa
L’amu kuro nitõto,
A tu irora wa
Tobehe, ki iku wa
Dabi ọmọ lękun,
T’oși’kun orun fun wa
Si iye aikú mọ.