AJINDE JESU KRISTI
- JESU Kristi ji loni,
Enia at’angeli wi,
Gbayo nyin tișegun ga,
Orun, aiye korin dã’ - Isé si idande tan,
Ija on isegun tan,
Orun ki dokunkun mọ,
Orun ko wọ l’eję mọ. - Eso ami n’iboji
L’asan, nigbati On ji,
‘Lekun isa oku și,
Qlà ona Paradis - Iku, itani re wà ?
Iboji ‘segun re wà?
Oba ogo si tun yè,
Iku rè da wa n’ide.