IJIYA JESU KRISTI
- Wo ade egan lori
Olugbala t’aiye,
An yin (i) nitori ore,
Tofi han f’araiye;Enu ya mi ni riro
Ijiya Jesu mi,
Mo ni iru ife’wo
Bi ifę Jesu mi? - Oluwa! mo mọ ẹgan
T’ ‘oru ni Golgata,
L’egan, t’Olorun gbesan,
Lara re nipo wa;
Bệ ni adari re ji
Eyi, t’ajigbese,
Ki awa, k’ole mã ri
Iye nipo egbe. - Olugbala ki l’emi
Wi niti ore re?
Gba ebọ ‘dupe t’emi
Lòrç, n’iwa rere ;
Titi emi of ope
Fun ‘o ni orun rẹ,
Nigba t’emi–lailese
Yio sin ‘o logo rẹ.