IJIYA JESU KRISTI
- NIGBA ti mo wo igi ni,
Nibi ti olugbala ku,
Ohun mi emi koka si,
Ogo mi ni mo b’egan lù. - Emi ko gbodo gbękę le,
Bikosę ninu iku rè,
Ohun asan, t’on t’afẹ rè
Mo gan, nitori eję rè. - Wo! t’ori, t’owo, t’ese rè
Irora t’on t’ifę rę wá,
Iru ifę re kosi ri,
T’oteje ara re fun wa. - Bi gbogbo aiye ni t’emi,
T’emi bun (u) Jesu, ko to nkan,
Ife rè t’aika, t’aiso ri,
Gba gbogbo ọkàn lọwọ wa.