More

    ORIN11 – K’ayin Oluwa t’ologo

    IBI JESU KRISTI.

    1. K’ayin Oluwa t’ologo,
      Loni l’abi (i) saiyé,
      K’ayin (i) nitori ti omu
      Ododo wa s’aiyé.
    2. Awọn orile ede ni
      Nreti Oluwa nã,
      Nwọn fẹ ri ẹni t’awa ri,
      Ani Olugbala.
    3. Oba ati woli mimó
      Nwọn foju si ọna,
      N’ireti ati igbagbo
      Nwọn duro d’Oluwa.
    4. Şugbọn Eni ti nwọn reti,
      Ani Olugbala,
      Nigba ti wa ni awa ri (i)
      Anrohin (i) y’aiye ka.