ORIN 7 – Eje k’ayin Olorun wa

OLORUN ELEDA

  1. EJE k’ayin Olorun wa
    Eleda gbogbo enia
    At’eranko, at’eweko,
    Ati gbogbo nkan mi gbogbo.
  2. Otete se imolẹ nã,
    K’ole fi iye laiye han,
    Osi te oju orun lọ,
    Kamá s’ofurufu nipo.
  3. Enyin teloju, ewa, wo!
    Aťoșupa, at’ irawo,
    Lese ese l’ofi wọn si,
    Iye won ni ale ka bi?
  4. Eje k’awo aiye wa nã,
    Ewa re, ti ofi bora,
    Opo ju ogo Solomon,
    T’ologo j’awọn Oba lọ.
  5. Sugbon ju gbogbo rẹ lọ, wo
    Enia l’aworan rè bo :
    Emi ti Emi re ni nwọn,
    Ofun wọn n’imò atogbọn.
  6. Eje k’ayin Olorun wa,
    Toda wa ni dara dara;
    Eje ki gbogbo eda yin
    Eleda, t’oto fun iyin.