OJO ISINMI
- OLUWA tojo isimi,
Gbọ ti wa, pẹlu wa loni!
T’ awa npade fun adua,
Tangboro na, to fi fun wa. - Isimi laiye l’ororun,
Sugbon isimi t’ohun dùn,
Lãlã okàn wa fe ‘jo na,
T’ awa simi laileşẽ ‘da. - Laiponju, lailare l’awà,
Nib’ isimi, ti ombo wá,
Ese, ibi kĩ debe na,
Kiki alafia l’onsan. - Kos’ ija, kosi ‘dagiri,
Kos’ aniyan bi taiye yi,
Todapọ mọ ikorin wa,
T’ont’ ete aiku jade wá. - Berẹ ọjọ t’atinreti,
Afejumọ rẹ l’afë ri,
Ona buru yi l’afẽ yọ,
K’asun niku, k’aji layo.