ORIN OWURO.
- Oluwa la oru yi ja
Iwo ti pa wa mọ,
Asi tun ri imole la,
Fun ‘o latun bọwọ. - Pa wa mo la ojo yi ja,
Fapa rẹ tọ wa rẽ,
Awon, ani awọn na la,
T’ iwo pa mọ n’ ire. - Ki gbogbo òro, ona wa
So pe, ti re l’awà
K’ imole õto ninu wa
Niwaju aiye tàn.