C.M.S 7, H.C. t.H.C 258 S.M. (FE 22)
“Lale loro ati losan li emi o ma gbadura” Ps. 55:7
- Wa s’adura oro
Kunle k’a gbadura;
Adura ni opa Kristiani,
Lati b’Olorun rin. - Losan, wole labe
Apat’ aiyeraiye;
Itura ojiji Re dun,
Nigbat’ orun ba mu. - Je ki gbogbo ile,
Wa gbadura l’ale
Ki ile wa di t’Olorun,
Ati ‘bode orun. - Nigbati od’oganjo
Jek’a wi l’emi, pe
Mo sun, sugbon okan mi ji
Lati ba O sona. Amin