C.M.S 5, H.C 17, L.M (FE 21)
“Nigbawo ni iwo o to mi wa?” – Ps 101:2
- WA s‘odo mi, Oluwa mi
Ni kutukutu owuro
Mu k’ero rere so jade,
Lat’ inu mi soke orun. - Wa soda mi, Oluwa mi,
Ni wakati osan gangan;
Ki ‘yonu ma ba se mi ma,
Nwon a si s’osan mi d’oru. - Wa sodo mi, Oluwa mi,
Nigbati ale ba nle lo,
Bi okan mi ba nsako lo,
Mu pada, f’oju ‘re wo mi. - Wa sodo mi, Oluwa mi,
Li oru, nigbati orun
Ko woju mi; je k’okan mi
Ri simi je li aiya Re. - Wa sodo mi, Oluwa mi,
Ni gbogbo ojo aiye mi,
Nigbati emi mi ba pin,
Ki nle n’ibugbe lodo Re. Amin