C.M.S.2t, S. 634, CM (FE 20)
“Emi dubule, mo si su, mo si ji Nitori
Oluwa ti mi Iehin” – Ps. 3:5
- Ninu gbogbo ewu oru,
Oluwa l‘o so mi
Awa si tun ri’ mole yi
A tun te ekun ba. - Oluwa, pa wa mo l’oni,
Fi apa Re so wa;
Kiki awon ti ‘Wo pamo
L‘o nyo ninu ewu. - K’oro wa, ati iwa wa
Wipe, Tire l’awa,
Tobe t’imole otito
Le tan l‘oju aiye. - Ma je k’a pada lodo Re,
Olugbala owon
Titi a o f’oju wa ri,
Oju Re li opin. Amin