t. H.C.2 L.M(FE19)
- Mo ji, Mo ji, Ogun orun
K’emi l’agbara bi ti nyin
K’emi ba le lo ojo mi
Fun iyin Olugbala mi. - Ogo fun Eru‘ o so mi
To tu mi lara loju Orun
Oluwa ijo mo ba ku
Ji mi s‘iye ainipekun. - Oluwa mo tun eje je
Tu ese ka b’iri oro
So akoronu mi oni
Si f‘Emi Re kun inu mi. - Oro at’ise mi oni
Ki nwon le re bi eko Re
K’emi si f‘ipa mi gbogbo
Sise rere fun Ogo Re. Amin