ORIN 1- Oluwa la oru yi ja

ORIN OWURO.

  1. Oluwa la oru yi ja
    Iwo ti pa wa mọ,
    Asi tun ri imole la,
    Fun ‘o latun bọwọ.
  2. Pa wa mo la ojo yi ja,
    Fapa rẹ tọ wa rẽ,
    Awon, ani awọn na la,
    T’ iwo pa mọ n’ ire.
  3. Ki gbogbo òro, ona wa
    So pe, ti re l’awà
    K’ imole õto ninu wa
    Niwaju aiye tàn.